Èkó inú èkó Ẹ́ẹyan ni ẹ́ Èkó, Happy New Year to you èkó wa Ìhun tó ń múnú èèyàn dùn Gbogbo dáadáa tí wọ́n ń ṣe láyé wàá bá wọn ṣe àdúà ẹ á gbà mo kí ẹ́ kú ọdún Ọláńrewájú o ṣeun mi àbúrò olórí ọ̀dọ́ Dèjì Okado ko bá mi ki Gbogbo yín ẹ tọ́jú Yayi ẹ bá n ki sílé Gbénbóyè ọmọ ànọ́bì o kú Ọmọ ànọ́bì Mushin O ṣé modúpẹ́ Àyìndé Ọmọ́gbọ́láhàn mi Mo fi àkókò yìí kí ẹ honourable Tunji Túnjí mi Àjùlọ #INSTRUMENTAL Honourable Túnjí mo f’àkókò yìí kí ẹ Honourable Túnjí Túnjí mi Àjùlọ Aṣojú Ọba gbogbo òmù àrán ọmọ Olúpo Àláelú Ọkọ Àdùnní Kafayatu mi fún t’ọjọ́ ìbí ẹ Túnjí Túnjí Ẹ̀mí ẹ á ṣe púpọ̀ ẹ̀ o Ọlá bàbá Abdul Moshood Babátúndé Bàbá Olamide Sheriff Túnjí Túnjí Bàbá Saidatu mi Adetóún Bàbá Tolání Basiratu Gbogbo àwọn ọmọ mi nílùú Canada wọ́n ní n kí ẹ Túnjí Aṣojú ọmọ òmù àrán ọmọ First aṣojú Ọba Ọmọ Karimu ọmọ t’òyèwọlé Ọmọ Ashabi Shifau Túnjí Túnjí Iṣan ọrùn tèmi Adégoróyè Arábámbí Lórúkọ́ gbogbo wa ilé iṣẹ́ K1 à ń kí ẹ Túnjí fún t’ọjọ́ ìbí ẹ àti Àdùnní Kafayatu mi Túnjí mi Àjùlọ Ọmọ sọgbódilé ọmọ asọ̀gbẹ́dìgboro ǹlẹ́ ọmọ asakìtàndọjà Túnjí mi Àjùlọ ah! Ọmọ sọgbódi (ọmọ sọgbódilé) Ọmọ sọgbódi (ọmọ sọgbódilé) Àjùlọ ò pin nílé bàbá ẹ (ọmọ sọgbódilé) Túnjí ẹ̀mí ẹ á ṣe púpọ̀ (ọmọ sọgbódilé) Àjùlọ ò pin nílé bàbá ẹ (ọmọ sọgbódilé) Ọkọ Àdùnní Kafayatu (ọmọ sọgbódilé) Adijatu Kubura Orítókẹ́ sweetie Aminatu Ọmọ mi Amina Aminatu mi, Èjìrẹ́ mo kí ẹ kí ẹ (Aminatu mi) 2025 ọdún ayọ̀ ló máa jẹ́ Gbogbo dáadáa téèyàn ń ṣe láyé lo ma gbé ilé ayé ṣe o (Aminatu mi) Èjìrẹ́ òyílà (Aminatu mi) Taiwo Kehin (Taiwo Kehinde) Taiwo Kehin (Taiwo Kehinde) Èjìrẹ́ Òyílà (Taiwo Kehinde) Ikú ò ní pa yín fún mi lọ́lá Ọlọ́hun o (Taiwo Kehinde) Aláyọ̀ká yí ọ da fún ọ tí ọ́ pọ̀ (Aláyọ̀ká) YÍ ọ da fún ọ tí ọ́ pọ̀ (Aláyọ̀ká) Ẹ gbàmí lọ́wọ́ modern Akéwì Mo rí i yín lọ́dún yìí màá ri yín o ní ẹ̀míì lọ́lá Ọlọ́hun Ọba nínú àlàáfíà ninú ọlá ńlá Aláyọ̀ká (Aláyọ̀ká) Àyọkà ọmọ mi (Aláyọ̀ká) Ẹ̀yin ni mo fẹ́ bá wí Bí èèyàn bá ń ṣe wàhálà, tó bá ń ṣiṣẹ́ Ngbọ́ ta lo yẹ kó kọ́kọ́ rí? Kó dúpẹ́ fún Ọlọ́hun Ọba Àìmọye ló fẹ́ irú èyí Alhaji Wasiu Ọlọ́hun ò mọ̀ wọ́n, àsìkò kálukú yàtọ̀ Àwa ń dúpẹ́ tiwa, a mọ̀-ọ́n lóore Orí ò lè wà kó má rìn lórí ọrùn Ọpẹ́ ni kẹ́ ẹ máa f’ojoojúmọ́ dú lọ́wọ́ Ọlọ́hun Ọba tó ní Risiq lọ́dọ̀ tó ń ṣe é lójoojúmọ́ Ẹ̀dá ò dàbí Ọlọ́hun Ọba ètùtù T’ọ́mọ ẹ̀dá bá dàbí Ọlọ́hun àwọn ẹ̀dá ò ní r’ọjò wọn ò ní jẹ́ a rílé ayé gbé Bẹ́ ẹ bá wá ti ṣé Bí èèyàn bá fẹ́ ná 200 million kò gbọ́dọ̀ dúró sọ pé ó di jọ́ tó bá ń pé k’óun tó na Wàá bẹ̀rẹ̀ tó bá possible láti 200 wàá bẹ́ẹ̀ síni da bí àjọ Níjọ́ kan ó máa pé Ìyẹn làwọn àgbà ọjọ́sí ni wọ́n ṣe ṣọ́ síwájú Wọ́n ní sùúrù ó lérè fún ẹni tó bá lọ́gbọ́n Tí ẹ bá ń ṣiṣẹ́ ẹ lo sùúrù ará mi Nǹkan mẹ́ta ni mo mọ̀ tó dùn Ọsàn dùn, Ọ̀gẹ̀dẹ́ dùn Ṣúgà dùn Mẹ́tẹ́ẹ̀ta wọ̀nyí téèyàn bá jẹ ẹ́ lájẹjù Àyìndé Ọmọ́gbọ́láhàn ó ní ihun tó ń ṣe lára Bí a bá ń jẹ iṣu ká máa yọ́ iṣu jẹ Àwọn tí ò gbọ́n ni wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀ jẹ gùdùgúdú Ó ku oníṣègùn tí ó ṣe ìwòsàn K1 De Ultimate ẹ jẹ́ á lo orí pípé Tẹ́ ẹ bá r’ówó kí èèyàn tó lè f’owó de nǹkan mọ́lẹ̀ á ṣe é díẹ̀ díẹ̀ Kò ní pẹ́ kò ní jìn á kún agolo Wàhálà yín ò ní já s’ásán Ẹniẹlẹ́ni kò ní gba ìṣe yín ṣe Àyìndé mi Wasiu B’éèyàn bá ní sùúrù ohun gbogbo ló ni Ẹni tó ní sùúrù ló ń jogún ayé Onísùúrù (ní ń jogún ayé) Èèyàn Tó bá ní sùúrù (yó jogún ayé) Ìgbà míì mà á máa wo araà mi Màá tún máa bèèrè question Ṣé ìwọ náà ni (ṣé ìwọ náà ni) Ṣé ìwọ náà ni (ṣé ìwọ náà ni) Ìyẹn ni mo rò, ni mo ṣe m’órin sẹ́nu (Adé orí ọ̀kín) Kìí ṣe mímọ̀ ọ́ ṣe ((Ọlọ́hun ló bá mi ṣé) Kì dẹ̀ ń ṣe mímọ̀ ọ́ ṣe (Ọlọ́hun ló bá mi ṣe) Kìí ṣe mímọ̀ ọ́ ṣe ((Ọlọ́hun ló bá wa ṣé) Kìí ṣe mímọ̀ ọ́ ṣe ((Ọlọ́hun ló bá wa ṣé) Wọ́n ti rò ẹ́ pín tẹ́lẹ̀ tẹ́lẹ̀ (Ọlọ́hun ló bá ẹ ṣé) Wọ́n ti rò ẹ́ pín tẹ́lẹ̀ tẹ́lẹ̀ (Ọlọ́hun ló bá ẹ ṣé) Wọ́n ti rò yín pín tẹ́lẹ̀ tẹ́lẹ̀ (Ọlọ́hun ló bá wa ṣé) Wọ́n ti rò wá pín tẹ́lẹ̀ tẹ́lẹ̀ (Ọlọ́hun ló bá wa ṣé) Kìí ṣe mímọ̀ ọ́ ṣe (Ọlọ́hun ló bá wa ṣé) Wọ́n rò mí pin tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ (Ọlọ́hun ló bá mi ṣé)