Lege, ṣé ò ń bá mi tọ́jú Kamal pẹ̀lú ST Lege Miami mo kí ẹ lege lege Mò ń wọ́kọ pàdé mò ń wáya lọ́dọ̀ Lege Ìwọ ọmọ obìnrin tí o bá ń wọ́kọ o Kẹ́ ẹ ṣé jẹ́jẹ́ ẹ lọ rí Lege Miami Èyí tí mo tiẹ̀ like jù tí wọ́n bá ń tackle ara wọn Ìyẹn ni mo like Àìmọye ọmọge tó mọ ohun tó fẹ́ kò dẹ̀ ń gba shit Àìmọye ọkùnrin pàápàá ó mọ irú aya tó ń wá Ìgbà tí ẹ bá fẹ́ra yín tán Kí lẹ má ń mú wá fún Lege? Alárinnà Proper alárinnà proper ni lege lege Torí Lege tí ẹ̀ ń wò yìí ọmọ company ni Ah! Kò dẹ̀ gba játijáti kò gba réderéde Àyìndé Ọba hookup lege lege Lege Miami (Ọba hookup lege lege) Bọ́lájí Àjàní, kòsí ihun tí ò lérè (Ọba hookup lege lege) Àjàní Bọ́lájí Bàsíà ìwọ ni bàbá Poco (Ọba hookup lege lege) Lege èèyàn Germany Waheed (Ọba hookup lege lege) Àwọn ti ṣómólú wọ́n ní n kí ẹ (Ọba hookup lege lege) Òun ló represent wa ní Ṣómólú Waheed ní Ṣómólú Bariga (Ọba hookup lege lege) Èèyàn bolikoko ọlọ́pàá Askari tó ń kọ Fújì Èèyàn ti lege Miami (Ọba hookup lege lege) Àwọn ti Ṣómólú wọ́n ní n kí ẹ o (Ọba hookup lege lege) Lege Miami àwọn ti Ṣómólú ní n kí ẹ (Ọba hookup lege lege) Àwa ti Fákóredé a kí ẹ o (Ọba hookup lege lege) Àwa ti Oguntolu a kí ẹ (Ọba hookup lege lege) Àwa ti Market market road àwa náà kí ẹ (Ọba hookup lege lege) Area mi mẹ́tẹ́ẹ̀ta nìyẹn ní Ṣómólú àwa t’Ògúntólú a kí ẹ (Ọba hookup lege lege) Àwa ti Fákóredé a kí ẹ o (Ọba hookup lege lege) Ọmọ ni lege Miami (Ọba hookup lege lege) Èèyàn Sodi Alágbo (Sodi Alágbo) Ṣé ò ń bá mi tọ́jú Sherifi Gbogbo yín ẹ kú ọdún Ẹ̀mí yín á ṣe púpọ̀ọ ẹ̀ mo kíi yín Àjàní Ọmọ́bọ́lájí ihun téèyàn bá mọ̀ Kó máa ṣé dáadáa o kó máa ṣé dáadáa Kòsí ìhun tí ò lérè Kò sí èyí tí ò dowó l’America Ìdí rèé tí a ní láti gbà fún Lege Àjàní ara àwọn ọmọ tá n wí rèé Bí a ṣe ń sọ ti lege lọ́wọ́ Apá tún wọlé Eléyìí náà ó bad Àjàní ṣé ẹ wo ibi tí ẹ bá ayé dé eléyìí ah! Chief Gaji, Gaji ó bad Gaji ń sọ bótò Apa ń sọ yéye Ali afisu Afisu ọmọ t’òkú ọ̀run ọkọ Mide baby Ọmọ mi ńkọ́? Happy New Year to you Ọmọ mi ńkọ́ nílé? Gbogbo yín ẹ kú ọdún ẹ̀míi yín á ṣe púpọ̀ ọdún láyé Al-Afeez Ìsẹ́yìn òrò ẹbẹdí o kú ilédè bàbá ẹ Apá! Ọmọ alálùbáríkà ṣá ni ẹ́ Apá! O ò dẹ̀ ní dọlárẹ̀yìn o Ọlọ́hun Ọba tó bá mi gbọ́wọ́ Fẹ́mi sókè á gbọ́wọ́ gbogbo yín sókè kò ní bàjẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́hun Ọba Àdúà á máa gbà Àmín Ah! Gaji o (Gaji o) Gaji eléyìí ó ń sọ bótò Gaji eléyìí ó ń sọ bótò Bọ́lájí a ní talent ní Nigeria gbogbo wọn ló ń ṣ’oríire Gbogbo wọn ni wọ́n ń ṣ’oríire Gbogbo wọn ni wọ́n ń ṣ’oríire (gbogbo wọn ni wọ́n ń ṣ’oríire) Askari gbogbo wọn ni wọ́n ń ṣ’oríire (Gbogbo wọn ni wọ́n ń ṣ’oríire) Ìkan ò wá ní ṣe ẹrú ara wọn lọ́lá Elédùmarè (Gbogbo wọn ni wọ́n ń ṣ’oríire) Ah! Ibrahim Chatta Ìkan òní ṣe ẹrú ara wọn lọ́lá Ọlọ́hun (Gbogbo wọn ni wọ́n ń ṣ’oríire) Fẹ́mi Adébáyọ̀ (gbogbo wọn ni wọ́n ń ṣ’oríire) Ah! Producer wọn rèé Afod Àjàní ṣé o rí àwọn ọmọ tí mo ń sọ o (Gbogbo wọn ni wọ́n ń ṣ’oríire) Kúnlé Afod àwọn ọmọ tí mò ń sọ o (Gbogbo wọn ni wọ́n ń ṣ’oríire) Bàbá aláàánú ọkọ àwọn arúgbó Bàbá Ọ̀yọ́ Báyọ̀ máa wolẹ̀ máa ràba Àwọn Director General (Gbogbo wọn ni wọ́n ń ṣ’oríire) Adébáyọ̀ ọmọ Tijani ah ah Máa wolẹ̀ Fẹ́mi Adébáyọ̀ (Gbogbo wọn ni wọ́n ń ṣ’oríire) Fẹ́mi ẹ̀yin lọmọ tí wọ́n ń sọ lọ́wọ́ lọ́wọ́ Ah ah Ẹ túálè fún Èsúsú Èsúsú mo túálè fún ẹ (Èsúsú mo túálè fún ẹ) Mo túálè fún ẹ (mo túálè fún ẹ) Ara àwọn ọmọ tí wọ́n ń sọ lọ́wọ́ lọ́wọ́ Èsúsú mo túálè fún ẹ (mo túálè fún ẹ) Gbogbo yín pátá pátá Ọlọ́hun tó bá mi gbé ọwọ́ọ yín sókè Kò ní rẹ̀yín nílé lọ́lá Ọlọ́hun Ọba Fẹ́mi happy birthday to you o kú oríire Ọmọ t’Adébáyọ̀ ọmọ t’Àdùkẹ́ Adébáyọ̀ ṣé a jọ ma? ṣé a jọ ma Fẹ́mi ṣé a jọ ma? ṣé a jọ ma? Bàbá Ọ̀yọ́ ṣé a jọ ma? ṣé a jọ ma? Fẹ́mi ṣé a jọ ma? ṣé a jọ ma? Ọkọ Iyán aládùkẹ́ ṣé a jọ ma? ṣé a jọ ma Àyìndé Wasiu ṣé a jọ ma ṣe àmọ́dún o? Shakada Ibro Shakada Adébáyọ̀ ṣé a jọ ma? ṣé a jọ ma? Òní la ó mu ọ̀la la ó mu Okay now agbára Fẹ́mi gangan ọmọ Adébáyọ̀ congratulations Ó ti kó gbogbo wa kéré sókè O ti kó táyà síwa lẹ́sẹ̀ Ìwọ nìkan lo láyà aláya méje (aláya méje) Aládùkẹ́ má fi bínú Aládùkẹ́ má fi bínú Aláya méje (aláya méje) Fẹ́mi aláya méje (Fẹ́mi aláya méje) Ṣùgbọ́n o adúpẹ́ lọ́wọ́ Èsúsú (adúpẹ́ lọ́wọ́ Èsúsú) Fẹ́mi ẹni pé ẹ kú Àyìndé wọ́n á kú di o (Ó di afọwọ́fọná afọwọ́fọná kì í ní’sinmi o) (Wérewère ní ń jó ká ìgboro) Afod Ọkọ Arúgbó Ẹní pé o kú Àyìndé á kú di o (Ó di afọwọ́fọná afọwọ́fọná kì í ní’sinmi o) (Wérewère ní ń jó ká ìgboro) Gbogbo yín pátá pátá Ọlọ́hun ti bá mi gbé ọwọ́ọ yín sókè Ẹ ò ní relẹ̀ lọ́lá Ọlọ́hun Ọba ìdùnnú Nigeria ṣá lẹ jẹ́ Ìdùnnú Nigeria ṣá lẹ jẹ́ o (Ìdùnnú Nigeria ṣá lẹ jẹ́ o) Ah! Ibrahim Chatta ó gbàmí lálejò sínú ilé ńlá náà Àgbàlá ilé ńlá l’Ọ́yọ̀ọ́ Ọlọ́hun bá mi gbé ọwọ́ọ yín sókè Júù bẹ́ẹ̀ lọ Ìdùnnú Nigeria ṣá lẹ jẹ́ o (ìdùnnú Nigeria ṣá lẹ jẹ́ o) Àjàní ó wù mí kó o dé Film village Ibrahim Chatta ó ṣe bẹbẹ Ìdùnnú Nigeria ṣá lẹ jẹ́ o (ìdùnnú Nigeria ṣá lẹ jẹ́ o) Afọdúnrìn ọkọ arúgbó Ìdùnnú Nigeria ṣá lẹ jẹ́ o (ìdùnnú Nigeria ṣá lẹ jẹ́ o) Orìn mi Àyìndé adé Àmọ̀pé olókun hú yáyá Mo lọ́jọ́ a dájọ́ ijó Bernard tí afẹ́fẹ́ ń ṣegi oko wẹ́ru wẹ́ru Gazaz igi inú oko ń lérí Ìràwọ̀ òní Mushin àjíná Ó ní bó wu òjò kó balè rọ̀ o Ó ní bójò bá le rọ̀ òun láti yalu’mi Ẹyẹ inú oko ń ṣìpẹ̀ Ó mà ní kó má ṣe lọ bá omi ja o Igi ò gbọ́ ó ń lérí igi pípa bá bínú Ẹ má ṣìpẹ̀ fún abuké Ẹ jẹ́ kígi ó ya lumi Nínú bá b’ómi á sì gbé igi lọ ọ̀rọ̀ rèé ẹ gbe yẹ̀wò Mo kọrin olókun hú yáyá ò ọlọ́sà ẹ mì lẹ̀ǹgbẹ̀ o Orin àkọ́kọ́kọ́dá Àyìnlá saliu ọmọ òkò ìrèsé Àyìndé Fatai mi ọmọ Ayọ̀ ọlá Yinni Yinni Yinni Yinni Yinni Yinni Yinni Yinni Babby Yinni Yinni Yinni Yinni Yinni Yinni Yinni Yinni Aya Babbison o Ọlá ọmọ Williams happy New Year to you Bàbá mi ìná ò ní tán owó ẹ Àmín àṣẹ Ọdún tuntun tá a bọ́sí yìí Gbogbo nǹkan tó ti níre níre lọ̀rọ̀ atare Ọlá ọmọ willy mi Williams Omọ àdúgbò mi (Ọmọ àdúgbò mi o) Olórí ẹgbẹ́ gbogbo Ajé Ọlá ọmọ àdúgbò mi (Ọlá ọmọ àdúgbò mi o) Ọmọ area mi ni ọmọ àdúgbò mi (Ọlá ọmọ àdúgbò mi o) Ọmọ Williams ọmọ àdúgbò mi (Ọlá ọmọ àdúgbò mi o)