Ìwàlẹwà ọmọ ènìyàn
(Ò bá dákun tọ́jú ìwà ẹ)
Ìwàlẹwà ọmọ ènìyàn
(Ò bá dákun tọ́jú ìwà ẹ)
Ìwà ọmọ ní ń mú ọmọ ṣe òkígbẹ́
Ẹ tọ́jú ẹ̀ dada
Ìwà loníwà mi wò
Ẹ̀ bá dákun tọ́jú ẹ̀ dada dada
Ìwà yìí ló ṣòwo
Ló s’ohun gbogbo ní mèremère dákun tọ́jú ẹ̀ dáadáa
Ìwà loníwà mi hù bí ò bá ti ṣí anybody mọ́
Ìwà ṣe pàtàkì pàtàkì
Àdélébáre àdélébáre àdélébáre àdélébáre àdélébáre Àrìnàkore àkòyàibi ìwà ẹni ni
Àmọ̀pé, oníwà ló nìwà o
Ìwà ọmọ ní ń mú ọmọ ṣe òkígbẹ́
Ò bá dákun tọ́jú ẹ̀ dada dada
Ìwá ṣe kókó láyée wa ò
Àyìnlá Fatai mi o
Olúbẹrí ọmọ ìyá oníyán
Ọmọ Brother Sadu mi
Secretary gbogbo Àgàràú brother Sadu l’Ágàràú area
Àgàràú ló jọ bí wa o
Ìgbà tí à ń jáde wéré
Ẹ̀yìn t’a tún jáde wéré tán Ajísàrì
Torí L’Ágàràú àdúgbò tiwa
Ẹ lọ béèrè ní’gboro èkó
Orúkọ tí àwa ń jẹ́ nínú Ajísàrì Fújì lawà Àyìndé L’Ágàràú area
Àwọn Mufu tó kọ́kọ́ jayé k’émi tó jayé
A bẹ̀rẹ̀ competition láti little Fújì, Little Fújì lawà
A gba ife ẹ̀yẹ organise musical competition
Mo bọ́ sí intermediate èmi pẹ̀lú ẹ náà ni
Láti Intermediate a gba ife ẹyẹ, a wọ senior category
Wọ́n wá gbé Fújì lawà lé mi lọ́wọ́ L’Ágàràú area o
Ọpẹ́ ni f’Ọ́lọ́hun Ọba àwọn tó fẹ́ dúró wọ́n dúró
Àwọn tí ò lè dúró gẹ́gẹ́ bí àdéhùn wọn pẹ̀lú Ẹlẹ́dàá kálukú
Wọ́n sún síwájú, wọ́n dẹ̀ rójú Ọlọ́hun Ọba
Àwa tí a wá dúró Ọlọ́hun ò fi wá sílẹ̀ Àyìnlá
Àìmọye tó kàwé o Bọ́lájí, ìwé ló gbé wọn d’America o
Ló gbé wọn dé Austria, ló gbé wọn dé Germany
Ló gbé wọn dé London Europe lápapọ̀ o
Ìwé ló gbé wọn dé Canada
Olúbẹrí Àyìnlá o ìwé kó làwá kà
A kàn r’ógo Ọlọ́hun Ọba ni ìlù gbé ẹ dé Canada
Ó gbé ẹ dé Australia, Spain
Ìlù gbé ẹ dé London, ó gbé ẹ d’America
Àyìnlá Olúbẹrí Ọba ìlù l’Àyìnlá
Ìbà fún àwọn ará iwájú
Bàbá wa Adio Kasumu Ishola Adé ọmọ Sanni
Rọ́rọ́ kan pọ́nùn kan mi ò gbàgbé ọjọ́
Ọjọ́ tí a lọ ṣílé
Bàbá òòṣà Àyìndé l’Ágége
Olúbẹrí kó ju ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún lọ
Kọ́kọ́rọ́ kan pọ́nùn kan
Kasumu Ishola ọmọ Sanni ó dìde bàbá ba k’ákàrà
Ó gbàá lọ́wọ́ Olúbẹrí Àyìnlá ó wá ṣ’àdúrà fún ẹ
Ọjọ́ náà o o ni wọ́n ti ń pe Fatai Àyìnlá Olúbẹrí ní kọ́kọ́rọ́ kan pọ́nùn kan
Ọmọdé ọjọ́un náà rèé o Fatai Àyìnlá wọ́n ń kí wọ́n ń kà o
Kọ́kọ́rọ́ kan pọ́nùn kan
Eléyìí jẹ́ opportunity gbogbo ẹ̀yin tó kù ẹ ṣe dáadáa
Kò sí ohun téèyàn ṣe láyé tí ò lérè
Gbogbo ẹ̀ ló lẹ́san
Kó o gún’yàn lọ́bẹ pàápàá ó lẹ́san ti ẹ̀
Stab èèyàn láti ẹ̀yìn ó lẹ́san
Oore ṣíṣe kìí gbé, ìkà náà ò dẹ̀ kí ń gbé
Mo kí ẹ kú oríire Olúbẹrí Fatai Àyìnlá
Àyìnlá, wọ́n kí wọ́n pà o
Àyìnlá Olúbẹrí wọ́n kí wọ́n pà o
Kọ́kọ́rọ́ kan pọ́nùn kan wọ́n ń kí wọ́n ń pà o
Àyìnlá Olúbẹrí wọ́n ń kí wọ́n ń pà o
Kọ́kọ́rọ́ kan pọ́nùn kan, wọ́n ń kí wọ́n ń pà o
Àyìnlá adé, wọ́n ń kí wọ́n ń pà o
Kòkòrò ọkàn pọ́nùn kan wọ́n ń kí wọ́n ń pa o
Ọba Sákárà, wọ́n ń kí wọ́n ń pà o
Ọba Sákárà, wọ́n ń kí wọ́n ń pà o
Kòkòrò ọkàn pọ́nùn kan wọ́n ń kí wọ́n ń pa o
Àyìnlá Olúbẹrí wọ́n ń kí wọ́n ń pa o
Ọmọ ọmọ ìyá oníyán, wọ́n ń kí wọ́n ń pa o
Ọmọ Bọ̀dá Sadu Àyìnlá , wọ́n ń kí wọ́n ń pa o
Àyìnlá Olúbẹrí, wọ́n ń kí wọ́n ń pà o
O kú oríire Àyìnlá wọ́n ń kí wọ́n ń pa o
Olúbẹrí wọ́n ń kí wọ́n ń pa o
Ògé dé ọlọ́jà ẹyẹ
Àkànkẹ́ Ògé mà ma dé ọlọ́jà ẹyẹ
Ògé dé ọlọ́jà ẹyẹ Ògé mà ma dé ọlọ́jà ẹyẹ
Adé orí ọ̀kín o Adé orí ọ̀kín o o
Ọlọ́hun Ọba o ṣé fún dídá tó o dáwa sí
Àánú Ọlọ́hun Ọba lórí wa
Ògé dé ọlọ́jà ẹyẹ
(Ògé mà ma dé ọlọ́jà ẹyẹ)