(Ma jó ma yọ̀)
Bí wọ́n pèmí lágbo Fújì ma ya lọ
Bí wọ́n pè mí lágbo Fújì ma ya lọ (ma jó ma yọ̀)
Bí wọ́n pè mí lágbo Fújì ma ya lọ (ma jó ma yọ̀)
Bí wọ́n pè mí lágbo Fújì ma ya lọ (ma jó ma yọ̀)
Bí wọ́n bá pè mí lágbo Fújì ma ya lọ (ma jó ma yọ̀)
Ìràwọ̀ òní mushin àjíná
Mo throw respect Àyìndé Wasiu arábámbí Ọba orin
Al - Akeem Bernado Bernado
Gbogbo yín ẹ kú ọdún
Oodua dà?
Gbogbo yín tí ẹ wá láti London àbí America àbí Canada
Ẹ káàbọ̀ sí Nigeria mo kí i yín o
Èjìrẹ́ ọmọ Ọba
Ọmọ ọmọ olówó èkó
Àrà ni gbogbo nǹkan nílée yín
Ìrókò nílàdó ọmọ ọ̀sànyìn’làwẹ̀
Èpò wẹ́rẹ́ lójúde t’ìlàdó
Kò ṣeé fọkọ́ ro kò ṣeé f’àdá ro ó
O ò kẹ̀dẹ̀ ró o ò kúrò níbẹ̀
Ọmọ ilá tí ò ti ibì kan wá
Ọmọ ọ̀nà ò ti ibìkan wọ ọjà
Òtòṣí ṣubú lọ́jà wọ́n b’ẹ̀rín rín
Bí olórí ilé bá ṣubú Ọmọ́gbọ́láhàn ẹ wo ẹkún lala
Mo kíi yín ẹ kú ọdún
Àmọ̀kẹ́ màmá Sójà Bọ́láńlé
Aya bàbá Sójà ẹ ẹ̀ ri iṣan ọrùn ẹ ni
Èèyàn Olúwafẹ́mi ṣótirẹ̀
Àyìnlá adé ọmọ Agara Ọlọ́hun ò jẹ́
Ìyá aláṣọ wa
Gbogbo yín ni mo kí ẹ kú ọdún Pastor dà?
Àdúà tí ẹ fi jagun fún wa o
Ẹ ṣọ́ fún wa lọ́rọ̀
Ẹ ní kí gbogbo wa ká lọ fún fún àdúà
Ẹ ní ká gbàá l’áàwẹ̀ wí pé ogun máa pọ̀ 2024
Ẹ ní ìjì máa jà ihun tó jẹ́ kí èmí gbà, etí inú
Èèyàn Tó bá ń rorí
Lára ohun tí ò gbọdọ̀ fi máa ṣeré
Ohun ni àdúà, agbára ò lè ṣé àdúà ló ń jẹ́ ìbẹlọ́hun Ọba o
Yí ó ṣe é fún gbogbo wa
Gbogbo àwọn tó ń fi àdúrà jagun
Ibi ọ̀tọ̀tọ̀ ọ̀rọ̀ kan ni wọ́n ń sọ o
Ọ̀rọ̀ kan ṣo ni wọ́n ń sọ
Wọ́n ní 2024 Dangote wọ́n ní ìjì máa jà
Wọ́n ní afẹ́fẹ́ máa fẹ́ wọ́n ní gbogbo ewéko á máa ṣe lágbálúgbú
Wọ́n ní omi á máa rú
Àyìndé ọmọ Ayọ̀ọlá
Wọ́n ní bó tilẹ̀ wù tó bó burú jù bẹ́ẹ̀ lọ o
Àgbọn orí ẹ̀, wọ́n ní kò ní jábọ́
Adamson, wọ́n ní ká ṣe mẹ̀dọ̀ ká f’ọwọ́ wọ́nú
Pé ohun tí ò tó ń bọ̀ wá ṣẹ́kù ọmọ osú
Wọ́n ní tí a bá fi la òkun náà já
Láti 2024 t’a fi wọ 25 wọ́n ní à á dúpẹ́ fún Elédùmarè à á sọpẹ́ fún Ọlọ́hun
Pastor Fáṣawẹ̀ ẹ má dákẹ́
Àdúà ló lè ṣé kì í ṣe agbára
Mo dúpẹ́ dúpẹ́ ẹ kú àdúrótì
Èṣìléwù èṣù pàtẹ ọjà ó ku bàbá ẹni tí ó ba na
Èèyàn t’Àyìnlá mi too much mi
Àyìnlá ọmọ Agara too much money kẹ́ ẹ bá mi ki
Ìwọ ni mo fi iṣẹ́ yẹn rán Ọmọ osú
Àyìnlá ọmọ Agara too much money kẹ́ ẹ bá mi ki
Adamson ṣé ọ̀rẹ́ ẹ ti dé láti Saudi
Ara àwọn tó ń fi àdúrà jagun nìyẹn o
Ó dé Saudi ó pè mí ó ní Alhaji ẹ fọkàn balẹ̀ àdúà ló lè ṣé
Eh eh
KC bó o ṣe má ń sẹ̀mí lọ́wọ́
2025 o tún dé bó o ṣe ń dé
Jí’ọ́n mọ̀
Àìmọye ni ò mọ ìtumọ̀ jí’ọ̀n mọ̀
Jí’ọ́n mọ̀ níṣe ló dàbí ọmọ àti ìkejì ọmọ
Tó bá possible ìsẹ̀yín ni wọ́n ń bímọ tí wọ́n ń ju ibi ọmọ nù
Àwọn tí wọ́n bí wa láyé àtijọ́ Àyìndé wọn kì í sọ ibi ọmọ nù
Ibi tí wọ́n bá gbe sí Ọmọ́gbọ́láhàn wọ́n á f’àmì si ni
Tó bá tújú bí ọmọ bá ń s’àárẹ̀
Tí wọ́n bá so gbogbo nǹkan fun
Ibi ibi ọmọ ni wọ́n máa lọ
Wọ́n á tùú wọ́n á bàá ara ọmọ á balẹ̀ á pé
Òhun ni ibi mi ọmọ mi o
Tàn-án mú àti Ajígbẹ́dà ọ̀rẹ́ mi Àyìndé Wasiu mi pẹ̀lú Jí’ọ́n mọ̀ ọmọ Bísọ́lá Jí’ọ́n mọ̀
Gbogbo yín k’órí bá mi dáa yín sí
Ikú òní pa yín fún mi
Àmọ̀kẹ́ mama Sójà mo kí ẹ Bọ́láńlé
Ọ̀rọ̀ lágbájá tó gbọ́ kùkù òjò
Ó bọ sẹ́yìnkùlé o d’omi inú agbada nù o
Christy ọ̀rọ̀ lágbájá tó gbọ́ kùkù òjò tó bọ́ sẹ́yìnkùlé o
Ó d’omi agbada nù o
Ìgbà tó yá ojú ọ̀run tó ṣú dẹ̀dẹ̀ kò tún padà rọ̀ o
Ó bẹ̀rẹ̀ sí ní y’òòrùn
Akin ọmọ Arógundádé Eluku
Gbogbo yín ni mo kí ọdún 2025 á san oore fún gbogbo wa
A ò ní ṣòwò àìpé
Bí a bá rán owó níṣẹ́ ńlá ni ó padà wá báwa nílé
Ọmọ Adétòrò
Àyìndé dà? Ayédáadé
Oníkiní púpọ̀ tó fi bí igba ọmọ
Ayédáadé alábínú a máa sá sí
Àyìndé mi Musiliu Ayédáadé
Ìjí jà afẹ́fẹ́ fẹ́ àgbọn ò jábọ́ débi omi àgbọn máa dànù
Adúpẹ́ fún Elédùmarè a dúpẹ́ f’Ọ́lọ́hun Ọba
Sọ fún Modina pé kó má dákẹ́ àdúà ìyá ọmọ méjì ẹdúnjọbí
Iṣu ọmọ á jóná fún ẹ jẹ
Kó o jíṣẹ́ mi fún Tọ́pẹ́ àti ọmọ Ojúṣàágbọlá mi Ọ̀gọ́jì
Toppy T Ìbàdàn, gbogbo yín ni mo kí kú ọdún
Kí ẹ bá mi kí ọmọ Ojúṣàágbọlá Aishatu kẹ́ ẹ bá mi ki
Oríyọmí Aminatu àbúrò Àṣàkẹ́ Ìdáyátù ọmọbọ́lájí
Àwọn ọmọ Adégoróyè mi ẹ̀gbọ́n Yọ̀mádé mi Sule olówó
Ẹ̀gbọ́n ti Al-amin ọmọ mi tọ̀míwá
Ẹ̀gbọ́n Fatimo, Ẹ̀gbọ́n Dámilọ́lá
Ó ṣe jẹ́ ìwọ ẹ̀gbọ́n ẹ̀gbọ́n wọn ò tiẹ̀ pè ẹ́ ní àbúrò èèyàn kankan, kílódé?
Ìwọ ẹ̀gbọ́n fún everybody Ọmọ́bọ́lájí Àṣàkẹ́ o ò dẹ̀ ní dọlárẹ̀yìn àbúrò àbẹ̀ní Monsuratu Ajíbádé
Àbúrò Àlàdé mi Azeez tó jẹ́ olórí ẹbí
O mà lucky gan àwọn méjì níwájú ìwọ nìkan
Ó wá lérò lẹ́yìn Ah!
Ẹ̀gbọ́n t’Àńjọláolúwa Àbíkẹ́
Ìgbà tó yá
Ojú ọ̀run tó ṣú dẹ̀dẹ̀ Àyìndé
Ó tún padà wọ̀
Ó bẹ̀rẹ̀ sí ní y’òòrùn o
Ayọ̀bámi ọmọ Awóyẹmí Ayọ̀ Radical ayọ̀ classical
Omọ Àmùdá Yusufu mi
Tayọ o ṣe ọdún eléyìí wà á ṣe ẹ̀míì tọmọ tọmọ
Ah obìnrin bí ọkùnrin ọmọ Surajudeen mi ọmọ Kẹ́shinró
Nílùú Ìjẹ̀bú Òde
Dérónkẹ́ Aisha, ẹ̀wà àgọ̀nyìn dà?
Ẹ̀wà àgọ̀nyìn dà?
Ẹ̀wà àgọ̀nyìn tí wọ́n fi Sugar sí
Stand to be recognised
Ẹ sọ fun rántí pé ẹnìkan ń bẹ tó ń retí oore Ọlọ́hun Ọba
Ìwọ nìkan kọ́
La dá ilé ayé fún
Àìmọye ló ń bẹ o tó ń retí oore Ọlọ́hun Ọba
Ìdùnnú wa lo jẹ́
O ò ní dọlárẹ̀yìn lọ́lá Elédùmarè lọ́lá Ọlọ́hun Ọba
Gbogbo yín ni mo dúpẹ́ fún ẹ̀yin ọ̀rẹ́ ẹ kú ọdún
Mo mọ̀ ọ́ lóore
Ká ríra wa bá
Ṣọ́balójú ó wá láti America mo kí ẹ ṣọ́balójú
Ah! Torí kíni ó ṣe dáadáa?
Adiso Àyìndé kíni ó ṣe dáadáa?
Ó ń dúpẹ́
Kín ni ó ṣe dáadáa?
Jaguar, kí ni ó ṣe dáadáa
Kín ni ó ṣe o (dáadáa)
Àní kí ni ó ṣe (dáadáa)
Ma ṣe dáadáa láyé mi (dáadáa)
Èmi ò mà ní ṣèkà o
Ayédáadé kí lo ó ṣe? (dáadáa)
Àní kí lo ó ṣe (dáadáa)
Ọlámilékan kí lo ó ṣe? (dáadáa)
Yíbíọ̀nà kí lo ó ṣe? (dáadáa)
Àní kí lo ó ṣe? (dáadáa)
Ah kí ló ó ṣe? (dáadáa)
Abby kí lo ó ṣe? (dáadáa)
Ìwọ ò mà níí ṣe ìkà o (dáadáa)
Ẹ jẹ́ ká máa ṣé (dáadáa)
Mo ní kí lo ó ṣe (dáadáa)
Kí lo ó ṣe (dáadáa)
Kí lo ó ṣe (dáadáa)
Kí lo ó ṣe (dáadáa)
Àní kí lo ó ṣe (dáadáa)