ékínátù (Live)-文本歌词

ékínátù (Live)-文本歌词

K1 De Ultimate
发行日期:

Sekinatu o (ah ah Sẹ̀kínátù )

Aláyélúwà, Ọba Adéwálé Tẹ́júọshọ́

Adédapọ̀ Déwálé

Tẹ́júọshọ́ (Tẹ́júọshọ́)

Ẹ kú àdúrótì, àna ti Eleganza Àkànní Ọkọ́ya (Tẹ́júọshọ́)

Olúṣọlá ọmọ Sanwoolú

Railway tún ti dé

(Railway tún ti dé)

Greenline tún ti dé

(Greenline tún ti dé)

Èèyàn Tó bá ń ṣe gbogbo eléyìí

Èèyàn ò lè máa ṣe gbogbo eléyìí k’áyé má polongo é

O ò dẹ̀ lè l’ọ́rẹ́ẹ́ ọ̀tá ni wà á máa ní lójoojúmọ́

Torí ẹni tó bá ń ṣe dáadáa kì í lọ́rẹ̀ẹ́

Ṣáà máa ṣe tì ẹ lọ Ọlọ́hun ló fún ẹ ṣe

Greenline tún ti dé

(Greenline tún ti dé)

Olúṣọlá Greenline tún ti dé

(Greenline tún ti dé)

Fún àǹfààní ará ìlú

(Ṣ’a jọ ma jẹ̀’gbádùn o)

F’áǹfàní aráàlú

(Ṣ’a jọ ma jẹ̀’gbádùn o)

Bàbá tún ń náwó Governor

Greenline ó ti dé

(Greenline ó ti dé)

Greenline ó ti dé

(Greenline ó ti dé)

Victoria Island Ẹ̀oẹ́ Express road TÓ fi wọ ìlú tiwa l’Ẹ́pẹ̀ẹ́

Ah! Greenline ó ti dé

(Greenline ó ti dé)

Adúpẹ́ lórúkọ àwọn bàbá mi o

Ẹlẹ́pẹ̀ẹ́ ń bẹ níbí

Governor, À ń dúpẹ́ lórúkọ gbogbo ilẹ̀ Akilẹ̀ Ìjẹ̀bú

À ń dúpẹ́ your excellency o ṣeun wa

Olúshọlá Greenline ó ti dé

Greenline ó ti dé

(Greenline ó ti dé)

F’áǹfàní aráàlú

(Ṣ’a jọ ma jẹ̀’gbádùn o)

Jídé, bí mo bá jí bó bá yọ̀ lókèrè sẹ́ o

(Ìbò ni o)

Ìyẹn gangan nìbò (Ìbò ni ò)

Babájídé (Ìbò ni ò)

Ọmọ Sanwoolú (Ìbò ni ò)

Èyí tó o ṣe yìí Ọlọ́hun Ọba lọba ẹlẹ́san

Àwọn ọmọ tìwọ náà wọ́n á rọ́lá lò

Ìwọ ti rọ́lá lò Àyìndé Wasiu o ò ní ṣubú lọ́lá Ọlọ́hun Ọba

Wàá rọ́lá lò títí dọjọ́ alẹ́

Àwọn ọmọ tì ẹ náà wọ́n á rọ́lá lò

Olúshọlá ọmọ Sanwóolú congratulations o ò ní kú ní kékeré

Láìpẹ́ ìwọ náà wàá ṣe 60 ẹ

Congratulations mo kí ẹ Jídé Jídé

Bàbá wọ́n ní wàá dàgbà

Wọ́n ní wàá dàgbà

Ṣé ẹ̀ ń ríṣẹ́ wa àbí ẹ ò ríṣẹ́ wa

(Ẹ wo ìgboro wò, ìgboro ni ẹ wò ṣé ẹ̀ ń ríṣẹ́ wa)

Ṣé ẹ̀ ń ríṣẹ́ wa, àbí ẹ ò ríṣẹ́ wa

(Ẹ wo ìgboro wò, ìgboro ni ẹ wò ṣé ẹ̀ ń ríṣẹ́ wa)

Olúayé Fújì ( ọ̀gá wa o)

Noimotu mi (Noimotu mi)

Ambassador Adégbóyèga ọmọ Bámiṣílé ìjìnlẹ̀

Owó ọkọ Àìná ó ní n kí bàbá

Ó ní ẹ kú oríire tòní

Ó ní ẹ̀míì yín á ṣe púpọ̀ọ ẹ̀ ọdún láyé

Ó ní kí n ki yín

Ó ní nínú àlàáfíà nínú ọlá ńlá

Gbóyèga ọkọ Àìná o

Ọbáfẹ́mi Hamzat

Ọmọ Ọba pàtàkì ọmọ àgbà rere o

Ó ní lórúkọ gómìnà

Ó ní kí n kí bàbá Chief Eleganza Ọkọ́ya

Ijó dijó Noimotu Afọláṣadé

Sir Olú ọmọ t’Ọ̀kẹ́owó

Olú o ò dẹ̀ ní dọlárẹ̀yìn àdúà ẹ ti gbà o ò ní ṣubú

Mo kí gbogbo Lagos white cap chiefs tí wọ́n ń bẹ níkàlẹ̀

John Mohmoh mo kí ẹ

Dr John Mohmoh ọkọ Ṣọlá mi sweetie

Àrẹ Abdulbashiru ọmọ Fákóredé

Ọ̀túnba Fẹ́mi Patron mi

His Excellency former Deputy Governor ní Lagos state

Ẹ kú àdúrótì mo ki yín

Ìyá wa erelú Abíọ́lá

A Bíọ́lá mi Dòsùnmú

Ìyá Ọba ẹ kú àdúrótì mo ki yín

Aṣúbíaró mi Mutiu ọmọ Ààrẹ Àjàó

Awo Àyìndé mọ́gbọ́láhàn arábámbí

Honourable Kamal Bashua Sesi Honourable ní Badagry mo ki yín

Àkànní adé (Àkànní adé)

Àkànní Eleganza (Àkànní adé)

Àkàndé Jẹ̀lílì ọmọ Anímáshaun mo kí i yín

Ẹ kú àdúrótì ọláńrewájú Brime ọkọ Engineer Sara

Ẹ kú àdúrótì mo ki yín

Chief Bísí ọmọ t’Ọlátilọ

Honourable Lámijù Akálà

Mo kí ẹ kí ẹ

O kú àdúrótì

Justice Adétọlá ọmọ t’Ògúntádé wọ́n ní n ṣá máa ṣ’àdúrà fún bàbá

Ká ri yín pẹ́ Àkànní mi Rasaki Eleganza Ọkọ́ya

Chief Adédoyin bàbá làgbámú

Ọkọ Ọlọ́huntóyìn mo ki yín

Baba Làgbámú (Bàbá Làgbámú)

Baba Làgbámú (Bàbá Làgbámú)

Baba Làgbámú (Bàbá Làgbámú)

Olúayé Fújì (ọ̀gá wa o)

Ọ̀rọ̀ ẹ kọ́ rárá rárá

(Ọ̀rọ̀ ẹ kọ̀ rárá rárá)

Ọba Saliu Bàbá Túndé Olówòrò Ẹlẹ́bọ l’ówòrò

Mo mà kí ẹ kí ẹ o ò ri bí

Ọba Kúṣẹ̀ńlá Adébọ́lá ànọ́bì Saheed Elégushi mo kí i yín

Abdul Wasiu Aláyélúwà gbogbo Ìrù Mayin ọkọ Mariamo mo kí ẹ

Òyìnbó dúdú níta tìgànmú

O ò dẹ̀ ní dọlárẹ̀yìn mo kí i yín

Abísógun Onírù tó nìrù

Mo kí ẹ Sule Maito

Rajia Shaaki àkọ́kọ́ Ajagungbadé

Jàfó oníbà ẹkùn (Sule Maito)

Mo kí engineer Sulemona Adékúnlé ọmọ Bámgbádé

Àrólé ọlọ́fin (Sule Maito)

Ọlọ́fin òfun fún mi níre (Sule Maito)

Àyìndé Olúayé ìbà arábámbí ọkùnrin ogun

(Àyìndé Olúayé ìbà arábámbí ọkùnrin ogun)

Àyìndé o Olúayé ibà arábámbí ọkùnrin ogun o

(Àyìndé Olúayé ìbà arábámbí ọkùnrin ogun)

Ká kọrin ká pèdè dá wọn lára yá

Iṣẹ́ orí rán mi ni mò ń jẹ́

Ká lùlù f’ọ́kọ rábàbà mújó jó

(La fí ń jẹ leader ní tiwa)

Ká lùlù f’ọ́kọ rábàbà mújó jó

(La fí ń jẹ leader ní tiwa)

Àyìndé o Olúayé ibà arábámbí ọkùnrin ogun o

(Àyìndé Olúayé ìbà arábámbí ọkùnrin ogun)

Ẹ bá mi dúpẹ́ lórí Fújì yìí Àyìndé

(Máyégún, ẹ bá mi dúpẹ́)

(Ẹ bá mi dúpẹ́ oh eh ará mi)

(Ẹ bá mi dúpẹ́ lórí Fújì yìí o)

Ẹ bá mi dúpẹ́ lórí Fújì yìí Àyìndé

(Arábámbí, ẹ bá mi dúpẹ́)

(Ẹ bá mi dúpẹ́ oh eh ará mi)

(Ẹ bá mi dúpẹ́ lórí Fújì yìí o)

Olásúnkànmí Àyìndé (Adégoróyè mi o)

Olásúnkànmí Àyìndé (olórí ọmọ Ọba níjẹ̀bú o)

(O sọ Fújì yìí dẹ̀rọ̀ ṣèbí bí ẹrú là bá máa ṣe o)

(Ẹ bá mi dúpẹ́)

(Ẹ bá mi dúpẹ́ oh eh ará mi)

(Ẹ bá mi dúpẹ́ lórí Fújì yìí o)

Ìdùnnú Ọkọ́ya sweetie Noimo

Ihun tí èèyàn bá ní tó ń múnú ẹ̀ dùn

Òhun ló fi ń yangàn síwájú Ọlọ́hun Ọba

Afọláṣadé mo wá ń bẹ̀ ẹ́ Ọlọ́hun Ọba

Bo ṣe ń tọ́jú bàbá mi

Wàá giùn lẹ́mìí nínú àlàáfía nínú ọlá ńlá

Nnkan kan ò ní ẹ ẹ́ ṣe Afọláṣadé

Áńgẹ́lì Eleganza l’Afọláṣadé mi Noimo

Noimotu o dára lọ́mọ Noimotu o

(Bí ẹ̀rín ló fi ń wu ni bí ẹwà a ò lè sọ)

Afọláṣadé o mà dára lọ́mọ Noimotu o

(Bí ẹ̀rín ló fi ń wu ni bí ẹwà a ò lè sọ)

B’ọ́kùnrin bá jẹ́ gbajúgbajà

(Ó da kó gbé ọmọ tó da níyàwó)

(Noimo gbajúmọ̀ lọ́mọ ó sì tún ṣòwò abiamọ)

Baàmi Àkànní

B’ọ́kùnrin bá jẹ́ gbajúgbajà

(Ó da kó gbé ọmọ tó da níyàwó)

(Noimo gbajúmọ̀ lọ́mọ ó sì tún ṣòwò abiamọ)

Fọláṣadé o dùn ún wò lọ́ọ̀dẹ̀ o

O ṣe é bá nílé

Aṣọ tí wọ́n ń mú lọ sóde níjọ́ ọdún

Bàtà tí wọ́n ń wọ̀ sẹ́sẹ̀ tó nene pinpin

Nìwọ mú lọ síta ọjà lọ fi jẹun

Ẹní pé o kú o nílẹ̀ yìí o

Yeh orí oyè akóyọyọ ló máa pá

Noimotu mi Noimotu mi

Noimotu mi adùnńbárìn má tòṣì Olúwa ò ní jẹ́ o tẹ́

(Ẹní pé o kú o nílẹ̀ yìí o)

(Yeh orí oyè akóyọyọ ló máa pá)

Bo ṣe ń bá mi tọ́jú bàbá mi

Afọláṣadé kiní kan kò ní ṣe ẹ́

Mo kí ẹ kí ẹ Fọláṣadé Noimo

Mo mà kí ẹ kí ẹ Fọláṣadé Noimo

Aya Àkànní Rasaki mi o

Aya Àkànní Rasaki mi o

Aya onílé ajé Fọláṣadé tìẹ yàtọ̀ o

(Ẹ̀rù ò mà í b’odò àyà í b’ọlọ)

(Ẹ̀rù ò mà í b’odò àyà í b’ọlọ)

(Ẹ̀rù ì í ba ẹrù ì ba, Ẹ̀rù ì í ba Soldier bógun bádé)