Aar kàànì kyá (Live)-文本歌词

Aar kàànì kyá (Live)-文本歌词

K1 De Ultimate
发行日期:

Baàmi Àkànní Rasaki ọmọ Ọkọ́ya o

Baàmi Àkànní ọmọ eléèyàn

Ọlọ́hun Ọba lọlọ́pẹ́

Lórí Àkànní mi Rasaki ọmọ onílé ajé

Àkànní ọmọ eléèyan

Àkànní Rasaki mi Eleganza Ọkọ́ya

Ọlọ́hun Ọba o ṣé

Torí pé àánú Ọlọ́hun Ọba dúró làa ṣe rọ́pẹ́ dá

Ọpẹ́ lọpẹ́ rẹ ò

Ọlọ́hun ọpẹ́ lọpẹ́ rẹ

Ayé ò bá yẹ̀yẹ́ wa o bàbá ló bá wa ṣé

(Ọpẹ́ lọpẹ́ rẹ ò, ọpẹ́ lọpẹ́ rẹ)

(Ayé ò bá yẹ̀yẹ́ wa o bàbá ló bá wa Ṣé)

Lénìí ọ̀nà ọpẹ́ wa pọ̀

Ìdí rèé tí a fi f’ọpẹ́ f’ìyìn fún Elédùmarè tí a fi ògo fún bàbá

Lórí baàmi ọmọ onílé ajé

Ààrẹ tìlú Èkó, Chief Eleganza Ọkọ́ya

Ọdún márùn-ún sẹ́yìn, ẹ jẹ́ n gbọ́rọ̀

Ọdún márùn-ún sẹ́yìn, ibi a gbé wá náà rèé

Àti Àkànní Olódó idẹ Àkànbí

Baàmi Àkànní onílé ajé

À ń dúpẹ́ lọ́jọ́ náà, fún oore t’Ọ́lọ́run Ọba ṣe o lórí ogún mẹ́rin

Ọjọ́ náà rèé bí àná

Aṣíwájú èkó tí à ń wí nígbà yẹn o òun ni current President

Ọ̀rọ̀ tí ẹ sọ lọ́dún márùn-ún ó ṣẹ tàbí ò ṣẹ

Ọlọ́hun lọlọ́pẹ́ ọ̀nà ọpẹ́ ẹ yín di púpọ̀

2024, ìní jà afẹ́fẹ́ ń fẹ́, ó ń hú igi tegbò tegbò ṣùgbọ́n àgbọn jábọ́ lórí igi Ọmọ́gbọ́láhàn mi kò d’omi inú àgbọn nù

Baàmi Àkànní onílé ajé atórí ẹni tí ò sùn wọ̀n ṣe Àkànní adé

Eleganza bàbá mi

Ọlọ́hun Ọba o ṣé fún dídá tó o da yín sí

President Ọbásanjọ́ ti sọ̀rọ̀

Wọ́n ní ọdún mẹ́wàá èní àwa yín ni

Wọ́n ní ọdún mẹ́ẹdógún èní àwa yin ni

His Excellency Governor ti ìpínlẹ̀ Èkó

Ó ní ọdún mẹ́ẹdógún èní àwa yín ni

Ṣé a jọ máa ṣe lọ́lá Elédùmarè lọ́lá Ọlọ́hun Ọba nínú àlàáfíà nínú ọlá ńlá

Bí Ọlọ́hun bá ní bí òun ṣe máa ṣé

Ènìyàn tí yó padà kiòsí àṣẹ lọ́wọ́ Ọlọ́hun Ọba ní

Àkànní ko ko ko ko lara ọta á máa le

Ìgbà tí Noimo bá ń ṣẹ̀mí tí Adija Oritókẹ́ bá ń ṣẹ̀mí

Ẹ̀mí i yín á gùn nínú àlàáfíà nínú ọlá ńlá Eleganza Ọkọ́ya lórúkọ Aṣíwájú President Federal Republic of Nigeria

Àkànbí ní kí n ki yín, ó ní kí n ki yín dáadáa

Kí n ki yín gbèje gbéjọ ó ní òun dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́hun

Ẹ Kú àdúrótì

Ó ní n ki yín, ó sì ní ẹ kú oríire

Baàmi ẹ̀míì yín á ṣe púpọ̀ ẹ̀

Aṣíwájú mó ní n dúpẹ́

Àkànní adé (Àkànní adé)

Onílé ajé Ọkọ́ya (Àkànní adé)

Tímọ́tímọ́ Chief Adédoyin bàbá Làgbámú Prince

Baàmi Àkànní Rasaki (onílé ajé)

Baàmi Àkànní Rasaki (onílé ajé)

Àrẹ̀mọ Olúṣẹ́gun ọmọ t’Ọ̀ṣọbà

Wọ́n ní kí n ki yín

Àwọn náà wọ́n sọ̀rọ̀, wọ́n ní ọpẹ́ ló yẹ Ọlọ́hun o (onílé ajé) Prince Samuel Adédoyin bàbá Làgbámú ọkọ olorì Olúwatóyìn wọ́n ní kí n ki yín

Aláṣẹ Peniel Properties, wọ́n ní ẹ ṣe ọdún eléyìí, ẹ ó ṣ’ẹ̀míì tọmọtọmọ

Àkànní Eleganza mi

Mohmoh ó ní kí n ki yín òun àti ìyàwó ẹ̀

Adéṣọlá àwọn méjèèjì wọ́n ní n ki yín

John Mohmoh, a ti ń ríra lójoojúmọ́ lọ́rọ̀ Àkànní

Ìwọ náà ẹ̀mí ẹ á gùn nínú ọlá ńlá

Ìwọ náà á dàgbà pẹ̀lú Déṣọlá

Chief Olúṣẹ́gun Àrẹ̀mọ ọkọ ọmọ Ọba Berry

Baàmi alábínú a máa sá sí, ẹ mà kú àdúrótì o

Nkiru Baby ìwọ náà o mà kú àdúrótì

Mo! Mosúnmọ́lá mo kí ẹ

Ẹ kú àdúrótì Àkànní Ọkọ́ya

Mo wá kí ọmọ Ọ̀kẹ́owó Chief Olú Happy New Year to you

O kú àdúrótì baàmi Àkànní

Ìwọ náà á dàgbà nínú ọlá ńlá

Your excellency Governor Babájídé Olúshọlá mi ọmọ Sanwoolú

Ọdún márùn-ún ijọ́sí ibí ṣá la wà ọmọ Anífowóse tí a gbé ń jó àti Àkànní adé mi

Máa bẹ máa bẹ ọ̀bẹ ní ń bẹ’ṣu ìwọ lo ó máa wà nínú ọlá ńlá Olúshọlá Àyìndé kìní kankan kò ní ṣe ẹ́

Ọmọ Sanwoolú ti sọ̀rọ̀ atúnlùúṣe atúnlùútò lórí ọ̀nà yìí

Ọlọ́hun kó fún ẹ ṣe ju bẹ́ẹ̀ lọ o

Àdúà ẹ á máa gbà síwájú

Ojú ọmọ gidi lo jẹ́ fún Aṣíwájú ọ̀gá mi Àkànbí adé

Justice Adéṣọlá mi bàbá wa

Ẹ mà kú àdúrótì o

Ẹ̀yin làgbà tó tó oròó lọ̀

Ẹ kú àdúrótì baàmi Àkànní Ọkọ́ya onílé ajé

A máa ri yín bá pípẹ́ lowú ń ṣ’arọ́ judge Adéṣọlá mi bàbá mi

Túndé ọmọ Ọ̀ṣínọ́wọ̀ sharafa Babátúndé

Ikòròdú Ọ̀gá ọmọ òriwù ọmọ Ẹ̀lúkúmẹdẹ́

O kú àdúrótì wàá gùn lẹ́mìí nínú àlàáfíà nínú ọlá ńlá

Ìlu ẹ̀ dà?

Balógun Dodo bàbá wa Àrẹ̀mú Ọbásanjọ́

A rí màmá a ti rí bàbá Àrẹ̀mú olówu òdùrú atúwọnká níbi wọ́n gbé dáná irọ́

Dòdòńdáwà Balógun ẹ kú àdúrótì Eleganza Ọkọ́ya

Your Excellency Deputy Governor owó ọkọ Fọláṣadé

Ẹ kú àdúrótì Eleganza Ọkọ́ya

Hamzat, mo kí ẹ kí ẹ Muhammad Kadiri Ọbáfẹ́mi Quadri

Ọdún márùn-ún ìjọ́sí íṣe lajọ kẹ́gbẹ́ síbí

Torí Àkànní Eleganza Ọkọ́ya

Aya mi dáadáa pípẹ́ lowú ń ṣ’arọ́ inú ẹ á dùn títí dọjọ́ alẹ́

Happy New Year to you ayaba

Your excellency ẹ kú àdúrótì mo kí i yín

Mo gba ara tiyín mo fi kí Governor Governor Dàpọ Abíọ́dún

Noimotu aya tiwa níjẹ̀bú òde Noimo

Ọmọ ọlọ́tà odò mi ọmọ arọ́dẹdẹ wọmi

O ò dẹ̀ ní dọlárẹ̀yìn iṣu ọmọ á jìnà fún ẹ jẹ

Onílé ajé (onílé ajé)

Florence mo kí ẹ kí ẹ (onílé ajé)

O dúró o múlé dání

Bàbá olówó, Tony mi (Tony mi)

Omọ Elumelu o kú àdúrótì (Tony mi)

O kú àdúrótì (Tony mi)

Alhaja Muibatu kí ẹ kí ẹ (Muibatu mi)

Ọmọ Gbàdàmọ́sí mi Sule (Muibatu mi)

Muiba ọmọ Gbàdàmọ́sí mi (Muibatu mi)

Ìkòròdú ọ̀gá ọmọ oríwu (Muibatu mi)

Fẹ̀yìntọlá mo kí ẹ kí ẹ (Muibatu mi)

Fẹ̀yìntọlá aya adájọ́ àgbà ìyá mi alábínú a máa sá sí

Ẹ kú àdúrótì (Eleganza mi)

Ah! Àkànní Ọkọ́ya (Eleganza mi)

Àkànní Ọkọ́ya (Eleganza mi)

Aya Ìbíkúnlé ọmọ Ámósùn ọdún márùn-ún a jọ ń bẹ níbí níjọ́sí náà

Máa bẹ máa bẹ ọ̀bẹ ní ń bẹ’ṣu ẹ̀yin la máa rí

Ṣé ò ń bá mi tọ́jú brother mi sílé

Ìbíkúnlé ọmọ Ámósùn mi

SST Lagos State ẹ kú àdúrótì mo ki yín

Ìyá ra, mo mà kí ẹ kí ẹ

Alhaja Bala Muinatu Shagaya o

Muina n ó máa pè ẹ́ o

Muinatu n ó máa pè ẹ́ o

Happy New Year to you Muina ọlọ́rẹ

Ẹ mà kú àdúrótì onílé ajé

Muinatu mi (Muinatu mi)

Mosúnmọ́lá ó yá jẹ́ n ríjó ọwọ́ ẹ o (Mosúnmọ́lá baby)

Mosúnmọ́lá, ìyà kan ò mà ní ẹ ẹ́ jẹ o (Mosúnmọ́lá baby)

Mo baby o you're beautiful

Mo baby o (o wà Candor)

Mo baby o (o wà Candor)

Mo baby (o wà Candor)

Mo! ó yá ọmọge wá jó

Ọmọge wá jó

Ọmọge wá jó

Jẹ́ á jó talazo extension (ọmọge wá jó)

Nkiru jẹ́ á jó talazo extension (ọmọge wá jó)

Ó yá jẹ́ á jó talazo extension (ọmọge wá jó)

Shukushuku bambam (ẹni tó bá wú kó bẹ́)

Shukushuku bambam (ẹni tó bá wú kó bẹ́)

Ó yá jẹ́ á jó talazo extension (ọmọge wá jó)